Luku 4:13
Luke 4:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ fun sá à kan.
Luke 4:13 in English
Luke 4:13 · Berean Standard Bible
When the devil had finished every temptation, he left Him until an opportune time.
Context
11àti pé ní ọwọ́ wọn ni wọn ó gbé ọ sókè,
kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ” 12Jesu sì dáhùn ó wí fún un pé, “A ti kọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ” 13Nígbà tí èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ fun sá à kan. 14Jesu sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Galili, òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. 15Ó sì ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.