Luku 3:13
Luke 3:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”
Luke 3:13 in English
Luke 3:13 · Berean Standard Bible
“Collect no more than you are authorized,” he answered.
Context
11Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” 12Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?” 13Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.” 14Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?”
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.” 15Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Johanu, bí òun ni Kristi tàbí òun kọ́;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.