Luku 24:34
Luke 24:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn si wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Simoni!”
Luke 24:34 in English
Luke 24:34 · Berean Standard Bible
and saying, “The Lord has indeed risen and has appeared to Simon!”
Context
32Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!” 33Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn. 34Wọn si wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Simoni!” 35Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mí mọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà. 36Bí wọ́n sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí Jesu tìkára rẹ̀ dúró láàrín wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.