Luku 23:52
Luke 23:52 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọkùnrin yìí tọ Pilatu lọ, ó sì tọrọ òkú Jesu.
Luke 23:52 in English
Luke 23:52 · Berean Standard Bible
He went to Pilate to ask for the body of Jesus.
Context
50Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Josẹfu, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatea. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòtítọ́. 51Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn; Ó wá láti Judea, ìlú àwọn ará Arimatea, òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run. 52Ọkùnrin yìí tọ Pilatu lọ, ó sì tọrọ òkú Jesu. 53Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí. 54Ó sì jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, ọjọ́ ìsinmi sì kù sí dẹ̀dẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.