Native Bible

Luke 20:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé,

Luke 20:23 in English

Luke 20:23 · Berean Standard Bible

But Jesus saw through their duplicity and said to them,

Context

21Wọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lóòtítọ́. 22Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó òde fún Kesari, tàbí kò tọ́?” 23Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé, 24“Ẹ fi owó idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti ta ni ó wà níbẹ̀?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.” 25Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Kesari fún Kesari, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.