Native Bible

Luke 20:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Tàbí ta ni ó fún ọ ní àṣẹ yìí?”

Luke 20:2 in English

Luke 20:2 · Berean Standard Bible

“Tell us,” they said, “by what authority are You doing these things, and who gave You this authority?”

Context

1Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹmpili tí ó sì ń wàásù ìyìnrere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà dìde sí i. 2Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Tàbí ta ni ó fún ọ ní àṣẹ yìí?” 3Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi pẹ̀lú yóò sì bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan; ẹ sì fi ìdáhùn fún mi. 4Ìtẹ̀bọmi Johanu, láti ọ̀run wá ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.