Luku 20:15
Luke 20:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tì í jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á. “Ǹjẹ́ kín ni olúwa ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn?
Luke 20:15 in English
Luke 20:15 · Berean Standard Bible
So they threw him out of the vineyard and killed him. What then will the owner of the vineyard do to them?
Context
13“Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn yóò bu ọlá fún un.’ 14“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbèrò pé, ‘Èyí ni àrólé; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa.’ 15Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tì í jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á.
“Ǹjẹ́ kín ni olúwa ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn? 16Yóò wá, yóò sì pa àwọn alágbàtọ́jú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn.”
Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n ní, “Kí a má ri i!” 17Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:
“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé’?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.