Luku 2:49
Luke 2:49 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri? Ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?”
Luke 2:49 in English
Luke 2:49 · Berean Standard Bible
“Why were you looking for Me?” He asked. “Did you not know that I had to be in My Father’s house *?”
Context
47Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀. 48Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n, ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, baba rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbànújẹ́ wá ọ kiri.” 49Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri? Ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?” 50Ọ̀rọ̀ tí o sọ kò sì yé wọn. 51Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Nasareti, sì fi ara balẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.