Luku 19:41
Luke 19:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó síjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí,
Luke 19:41 in English
Luke 19:41 · Berean Standard Bible
As Jesus approached Jerusalem and saw the city, He wept over it
Context
39Àwọn kan nínú àwọn Farisi nínú àwùjọ náà sì wí fún un pé, “Olùkọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.” 40Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí fún wọn pé, “Mo wí fún yín, bí àwọn wọ̀nyí bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn òkúta yóò kígbe sókè.” 41Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó síjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí, 42Ó ń wí pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ̀, lónìí yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí àlàáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ. 43Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.