Native Bible

Luke 19:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jẹ ọba lórí wa.’

Luke 19:14 in English

Luke 19:14 · Berean Standard Bible

But his subjects hated him and sent a delegation after him to say, ‘We do not want this man to rule over us.’

Context

12Ó sì wí pé, “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà. 13Ó sì pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mina mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ máa ṣòwò títí èmi ó fi dé!’ 14“Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jẹ ọba lórí wa.’ 15“Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́ òwò wọn. 16“Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina mẹ́wàá sí i.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.