Native Bible

Luke 19:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mina mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ máa ṣòwò títí èmi ó fi dé!’

Luke 19:13 in English

Luke 19:13 · Berean Standard Bible

Beforehand, he called ten of his servants and gave them ten minas.* ‘Conduct business with this until I return,’ he said.

Context

11Nígbà tí wọ́n sì ń gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó sì tẹ̀síwájú láti pa òwe kan, nítorí tí ó súnmọ́ Jerusalẹmu, àti nítorí tí wọn ń rò pé, ìjọba Ọlọ́run yóò farahàn nísinsin yìí. 12Ó sì wí pé, “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà. 13Ó sì pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mina mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ máa ṣòwò títí èmi ó fi dé!’ 14“Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jẹ ọba lórí wa.’ 15“Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́ òwò wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.