Luku 18:30
Luke 18:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”
Luke 18:30 in English
Luke 18:30 · Berean Standard Bible
will fail to receive many times more in this age—and in the age to come, eternal life.”
Context
28Peteru sì wí pé, “Sá wò ó, àwa ti fi ilé wa sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!” 29Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run, 30tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.” 31Nígbà náà ni ó pe àwọn méjìlá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Sá wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, a ó sì mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, nítorí Ọmọ Ènìyàn. 32Nítorí tí a ó fi lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́, a ó fi ṣe ẹlẹ́yà, a ó sì fi ṣe ẹ̀sín, a ó sì tutọ́ sí i lára.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.