Native Bible

Luke 17:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí gẹ́gẹ́ bí mọ̀nàmọ́ná ti í kọ ní apá kan lábẹ́ ọ̀run, tí sì í mọ́lẹ̀ ní apá kejì lábẹ́ ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ Ènìyàn yóò sì rí ní ọjọ́ rẹ̀.

Luke 17:24 in English

Luke 17:24 · Berean Standard Bible

For just as the lightning flashes and lights up the sky from one end to the other, so will be the Son of Man in His day.

Context

22Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí ẹ̀yin yóò fẹ́ láti rí ọ̀kan nínú ọjọ́ Ọmọ Ènìyàn, ẹ̀yin kì yóò sì rí i. 23Wọ́n sì wí fún yín pé, ‘Wò ó níhìn-ín!’ tàbí ‘Wò ó lọ́hùn ún!’ Ẹ máa lọ, ẹ má ṣe tẹ̀lé wọn. 24Nítorí gẹ́gẹ́ bí mọ̀nàmọ́ná ti í kọ ní apá kan lábẹ́ ọ̀run, tí sì í mọ́lẹ̀ ní apá kejì lábẹ́ ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ Ènìyàn yóò sì rí ní ọjọ́ rẹ̀. 25Ṣùgbọ́n kò lè ṣàìmá kọ́ jìyà ohun púpọ̀, kí a sì kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ ìran yìí. 26“Bí ó ti rí ní ọjọ́ Noa, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ Ọmọ Ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.