Luku 17:22
Luke 17:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí ẹ̀yin yóò fẹ́ láti rí ọ̀kan nínú ọjọ́ Ọmọ Ènìyàn, ẹ̀yin kì yóò sì rí i.
Luke 17:22 in English
Luke 17:22 · Berean Standard Bible
Then He said to the disciples, “The time is coming when you will long to see one of the days of the Son of Man, but you will not see it.
Context
20Nígbà tí àwọn Farisi bi í pé, nígbà wo ni ìjọba Ọlọ́run yóò dé, ó dá wọn lóhùn pé, “Ìjọba Ọlọ́run kì í wá pẹ̀lú àmì. 21Bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wí pé, ‘Kíyèsi i níhìn-ín!’ tàbí ‘Kíyèsi i lọ́hùn ún ni!’ sá à wò ó, ìjọba Ọlọ́run ń bẹ nínú yín.” 22Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí ẹ̀yin yóò fẹ́ láti rí ọ̀kan nínú ọjọ́ Ọmọ Ènìyàn, ẹ̀yin kì yóò sì rí i. 23Wọ́n sì wí fún yín pé, ‘Wò ó níhìn-ín!’ tàbí ‘Wò ó lọ́hùn ún!’ Ẹ máa lọ, ẹ má ṣe tẹ̀lé wọn. 24Nítorí gẹ́gẹ́ bí mọ̀nàmọ́ná ti í kọ ní apá kan lábẹ́ ọ̀run, tí sì í mọ́lẹ̀ ní apá kejì lábẹ́ ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ Ènìyàn yóò sì rí ní ọjọ́ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.