Native Bible

Luke 14:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ó má ba à jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà.

Luke 14:29 in English

Luke 14:29 · Berean Standard Bible

Otherwise, if he lays the foundation and is unable to finish the work, everyone who sees it will ridicule him,

Context

27Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi. 28“Nítorí ta ni nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀. 29Kí ó má ba à jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà. 30Wí pé, ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé, kò sì lè parí rẹ̀.’ 31“Tàbí ọba wo ni ó ń lọ bá ọba mìíràn jà, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbèrò bí yóò lè fi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) pàdé ẹni tí ń mú ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) bọ̀ wá ko òun lójú?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.