Native Bible

Luke 13:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, ojú ti gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, gbogbo ìjọ ènìyàn sì yọ̀ fún ohun ìyanu gbogbo tí ó ṣe.

Luke 13:17 in English

Luke 13:17 · Berean Standard Bible

When Jesus said this, all His adversaries were humiliated. And the whole crowd rejoiced at all the glorious things He was doing.

Context

15Nígbà náà ni Olúwa dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, olúkúlùkù yín kì í tú màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò ní ibùso, kì í sì í fà á lọ mu omi ní ọjọ́ ìsinmi. 16Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í ṣe ọmọbìnrin Abrahamu sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí Satani ti dè, sá à wò ó láti ọdún méjìdínlógún yìí wá?” 17Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, ojú ti gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, gbogbo ìjọ ènìyàn sì yọ̀ fún ohun ìyanu gbogbo tí ó ṣe. 18Ó sì wí pé, “Kín ni ìjọba Ọlọ́run jọ? Kín ni èmi ó sì fiwé? 19Ó dàbí hóró musitadi, tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì sọ sínú ọgbà rẹ̀; tí ó sì hù, ó sì di igi ńlá; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé orí ẹ̀ka rẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.