Luku 13:16
Luke 13:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í ṣe ọmọbìnrin Abrahamu sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí Satani ti dè, sá à wò ó láti ọdún méjìdínlógún yìí wá?”
Luke 13:16 in English
Luke 13:16 · Berean Standard Bible
Then should not this daughter of Abraham, whom Satan has kept bound for eighteen long years, be released from her bondage on the Sabbath day?”
Context
14Olórí Sinagọgu sì kún fún ìrunú, nítorí tí Jesu mú ni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pé, ọjọ́ mẹ́fà ní ń bẹ tí a fi í ṣiṣẹ́, nínú wọn ni kí ẹ̀yin kí ó wá kí á ṣe dídá ara yín, kí ó má ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. 15Nígbà náà ni Olúwa dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, olúkúlùkù yín kì í tú màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò ní ibùso, kì í sì í fà á lọ mu omi ní ọjọ́ ìsinmi. 16Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í ṣe ọmọbìnrin Abrahamu sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí Satani ti dè, sá à wò ó láti ọdún méjìdínlógún yìí wá?” 17Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, ojú ti gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, gbogbo ìjọ ènìyàn sì yọ̀ fún ohun ìyanu gbogbo tí ó ṣe. 18Ó sì wí pé, “Kín ni ìjọba Ọlọ́run jọ? Kín ni èmi ó sì fiwé?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.