Native Bible

Luke 1:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ yóò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu.

Luke 1:31 in English

Luke 1:31 · Berean Standard Bible

Behold, you will conceive and give birth to a son, and you are to give Him the name Jesus.

Context

29Ṣùgbọ́n ọkàn Maria kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kín ni èyí. 30Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria, nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run. 31Ìwọ yóò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu. 32Òun ó pọ̀, ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é, Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún. 33Yóò sì jẹ ọba lórí ilé Jakọbu títí láé; ìjọba rẹ̀ kì yóò sì ní ìpẹ̀kun.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.