Native Bible

Leviticus 8:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn èyí ló mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n, ó fi àmùrè dìwọ́n lára, ó fi fìlà dé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Leviticus 8:13 in English

Leviticus 8:13 · Berean Standard Bible

Then Moses presented Aaron’s sons, put tunics on them, wrapped sashes around them, and tied headbands on them, just as the LORD had commanded him.

Context

11Ó wọ́n díẹ̀ nínú òróró yìí sórí pẹpẹ lẹ́ẹ̀méje, ó ta òróró sórí pẹpẹ àti gbogbo ohun èlò àti agbada pẹ̀lú ohun tó gbé agbada yìí dúró láti lè yà á sí mímọ́, 12ó da díẹ̀ lára òróró ìtasórí yìí sórí Aaroni, ó sì yà á sí mímọ́. 13Lẹ́yìn èyí ló mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n, ó fi àmùrè dìwọ́n lára, ó fi fìlà dé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 14Ó sì mú akọ màlúù wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí ẹran náà. 15Mose pa akọ màlúù náà, ó sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí gbogbo ìwo pẹpẹ láti wẹ pẹpẹ náà mọ́. Ó da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ní ó ṣe yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.