Native Bible

Leviticus 6:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sọ fún Mose pé,

Leviticus 6:8 in English

Leviticus 6:8 · Berean Standard Bible

Then the LORD said to Moses,

Context

6Fún ìtánràn rẹ̀, ó gbọdọ̀ mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá fún àlùfáà, àní síwájú Olúwa, ẹbọ ẹ̀bi, àgbò aláìlábùkù, tó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́. 7Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún un ètùtù ìwẹ̀nùmọ́ níwájú Olúwa, a ó sì dáríjì í nítorí ohun tó ti ṣe tó sì mú un jẹ̀bi.” 8Olúwa sọ fún Mose pé, 9“Pàṣẹ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Èyí ni ìlànà fún ẹbọ sísun; ẹbọ sísun gbọdọ̀ wà lórí pẹpẹ láti alẹ́ di òwúrọ̀, kí iná sì máa jó lórí pẹpẹ 10kí àlùfáà sì wọ ẹ̀wù funfun rẹ̀ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ lára rẹ̀, yóò sì kó eérú tó wà níbi ẹbọ sísun tí iná ti jó lórí pẹpẹ, sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.