Lefitiku 6:10
Leviticus 6:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
kí àlùfáà sì wọ ẹ̀wù funfun rẹ̀ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ lára rẹ̀, yóò sì kó eérú tó wà níbi ẹbọ sísun tí iná ti jó lórí pẹpẹ, sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.
Leviticus 6:10 in English
Leviticus 6:10 · Berean Standard Bible
And the priest shall put on his linen robe and linen undergarments, and he shall remove from the altar the ashes of the burnt offering that the fire has consumed and place them beside it.
Context
8Olúwa sọ fún Mose pé, 9“Pàṣẹ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Èyí ni ìlànà fún ẹbọ sísun; ẹbọ sísun gbọdọ̀ wà lórí pẹpẹ láti alẹ́ di òwúrọ̀, kí iná sì máa jó lórí pẹpẹ 10kí àlùfáà sì wọ ẹ̀wù funfun rẹ̀ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ lára rẹ̀, yóò sì kó eérú tó wà níbi ẹbọ sísun tí iná ti jó lórí pẹpẹ, sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 11Nígbà náà ni yóò bọ́ aṣọ rẹ̀, yóò sì wọ òmíràn, yóò wá gbé eérú náà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó níbi tí a kà sí mímọ́. 12Iná tó wà lórí pẹpẹ gbọdọ̀ máa jó, kò gbọdọ̀ kú, ní àràárọ̀ ni kí àlùfáà máa to igi si, kí ó sì to ẹbọ sísun sórí iná, kí ó sì máa sun ọ̀rá ẹran ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.