Native Bible

Leviticus 4:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n awọ màlúù àti gbogbo ara rẹ̀, àti ẹsẹ̀, gbogbo nǹkan inú àti ìgbẹ́ rẹ̀.

Leviticus 4:11 in English

Leviticus 4:11 · Berean Standard Bible

But the hide of the bull and all its flesh, with its head and legs and its entrails and dung—

Context

9Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá wọn tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ pẹ̀lú kíndìnrín. 10Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń yọ ọ̀rá kúrò lára màlúù tí a fi rú ẹbọ àlàáfíà; àlùfáà yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ ẹbọ sísun. 11Ṣùgbọ́n awọ màlúù àti gbogbo ara rẹ̀, àti ẹsẹ̀, gbogbo nǹkan inú àti ìgbẹ́ rẹ̀. 12Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo ìyókù akọ màlúù náà ni kí ẹ gbé jáde síta lẹ́yìn ibùdó sí ibi tí a sọ di mímọ́ níbi tí à ń da eérú sí, kí ẹ sì sun wọ́n lórí iná igi, níbi eérú tí a kójọ. 13“ ‘Bí gbogbo àpapọ̀ ènìyàn Israẹli bá ṣèèṣì ṣẹ̀, tí wọ́n sì ṣe ohun tí kò yẹ kí wọ́n ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àpapọ̀ ènìyàn náà kò mọ̀ sí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n jẹ̀bi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.