Lefitiku 4:10
Leviticus 4:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń yọ ọ̀rá kúrò lára màlúù tí a fi rú ẹbọ àlàáfíà; àlùfáà yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ ẹbọ sísun.
Leviticus 4:10 in English
Leviticus 4:10 · Berean Standard Bible
just as the fat is removed from the ox of the peace offering. Then the priest shall burn them on the altar of burnt offering.
Context
8Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ nínú akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú àti gbogbo ohun tó so mọ́ wọn. 9Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá wọn tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ pẹ̀lú kíndìnrín. 10Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń yọ ọ̀rá kúrò lára màlúù tí a fi rú ẹbọ àlàáfíà; àlùfáà yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ ẹbọ sísun. 11Ṣùgbọ́n awọ màlúù àti gbogbo ara rẹ̀, àti ẹsẹ̀, gbogbo nǹkan inú àti ìgbẹ́ rẹ̀. 12Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo ìyókù akọ màlúù náà ni kí ẹ gbé jáde síta lẹ́yìn ibùdó sí ibi tí a sọ di mímọ́ níbi tí à ń da eérú sí, kí ẹ sì sun wọ́n lórí iná igi, níbi eérú tí a kójọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.