Lefitiku 26:40
Leviticus 26:40 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Bí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ti baba ńlá wọn, ìwà ìṣọ̀tẹ̀ wọn àti bí wọ́n ti ṣe lòdì sí mi.
Leviticus 26:40 in English
Leviticus 26:40 · Berean Standard Bible
But if they will confess their iniquity and that of their fathers in the unfaithfulness that they practiced against Me, by which they have also walked in hostility toward Me—
Context
38Ẹ̀yin yóò ṣègbé láàrín àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà. Ilẹ̀ ọ̀tá yín yóò sì jẹ yín run. 39Àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú yín ni yóò ṣòfò dànù ní ilẹ̀ ọ̀tá yín torí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ti àwọn baba ńlá yín. 40“ ‘Bí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ti baba ńlá wọn, ìwà ìṣọ̀tẹ̀ wọn àti bí wọ́n ti ṣe lòdì sí mi. 41Èyí tó mú mi lòdì sí wọn tí mo fi kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn. Nígbà tí wọ́n bá rẹ àìkọlà àyà wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá sì gba ìbáwí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 42Nígbà náà ni Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Jakọbu àti pẹ̀lú Isaaki àti pẹ̀lú Abrahamu, Èmi yóò sì rántí ilẹ̀ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.