Lefitiku 26:32
Leviticus 26:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò pa ilẹ̀ yín run dé bi pé ẹnu yóò ya àwọn ọ̀tá yín tí ó bá gbé ilẹ̀ náà.
Leviticus 26:32 in English
Leviticus 26:32 · Berean Standard Bible
And I will lay waste the land, so that your enemies who dwell in it will be appalled.
Context
30Èmi yóò wó àwọn pẹpẹ òrìṣà yín, lórí òkè níbi tí ẹ ti ń sìn, Èmi yóò sì kó òkú yín jọ, sórí àwọn òkú òrìṣà yín. Èmi ó sì kórìíra yín. 31Èmi yóò sọ àwọn ìlú yín di ahoro, èmi yóò sì ba àwọn ilé mímọ́ yín jẹ́. Èmi kì yóò sì gbọ́ òórùn dídùn yín mọ́. 32Èmi yóò pa ilẹ̀ yín run dé bi pé ẹnu yóò ya àwọn ọ̀tá yín tí ó bá gbé ilẹ̀ náà. 33Èmi yóò sì tú yín ká sínú àwọn orílẹ̀-èdè, Èmi yóò sì yọ idà tì yín lẹ́yìn, ilẹ̀ yín yóò sì di ahoro, àwọn ìlú yín ni a ó sì parun. 34Ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi fún gbogbo ìgbà tí ẹ fi wà ní ilẹ̀ àjèjì tí ẹ kò fi lò ó. Ilẹ̀ náà yóò sinmi láti fi dípò ọdún tí ẹ kọ̀ láti fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.