Lefitiku 25:24
Leviticus 25:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní gbogbo orílẹ̀-èdè ìní yín, ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìràpadà ilẹ̀ náà.
Leviticus 25:24 in English
Leviticus 25:24 · Berean Standard Bible
Thus for every piece of property you possess, you must provide for the redemption of the land.
Context
22Bí ẹ bá gbin èso yín ní ọdún kẹjọ, àwọn èso ti tẹ́lẹ̀ ní ẹ ó máa jẹ, títí tí ìkórè ti ọdún kẹsànán yóò fi dé. 23“ ‘Ẹ má ṣe ta ilẹ̀ yín ní àtàpa torí pé ẹ̀yin kọ́ lẹ ni ín, ti Ọlọ́run ni, ẹ̀yin jẹ́ àjèjì àti ayálégbé. 24Ní gbogbo orílẹ̀-èdè ìní yín, ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìràpadà ilẹ̀ náà. 25“ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín bá tálákà, dé bi pé ó ta ara àwọn ẹrù rẹ̀, kí ará ilé rẹ̀ tí ó súnmọ́ ọ ra ohun tí ó tà padà. 26Ẹni tí kò ní ẹni tó lè rà á padà fún un, tí òun fúnra rẹ̀ sì ti lọ́rọ̀, tí ó sì ní ànító láti rà á.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.