Lefitiku 24:6
Leviticus 24:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fà mẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó wúrà bọ̀. Èyí tí ó wà níwájú Olúwa.
Leviticus 24:6 in English
Leviticus 24:6 · Berean Standard Bible
and set them in two rows—six per row—on the table of pure gold before the LORD.
Context
4Àwọn Àtùpà tí wọ́n wà lórí ojúlówó ọ̀pá fìtílà tí a fi wúrà ṣe níwájú Olúwa ni kí ó máa jó lójoojúmọ́. 5“Mú ìyẹ̀fun dáradára, kí o sì ṣe ìṣù àkàrà méjìlá, kí o lo ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) fún ìṣù kọ̀ọ̀kan. 6Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fà mẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó wúrà bọ̀. Èyí tí ó wà níwájú Olúwa. 7Ẹ fi ojúlówó tùràrí sí ọnà kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìpín ìrántí láti dípò àkàrà, àti láti jẹ ẹbọ sísun sí Olúwa. 8Àkàrà yìí ni kí ẹ gbé wá síwájú Olúwa nígbàkígbà, lọ́ṣọ̀ọ̀ṣẹ̀, nítorí tí àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú ayérayé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.