Lefitiku 24:3
Leviticus 24:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn aṣọ ìkélé ti ibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Aaroni ti tan iná náà níwájú Olúwa, láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójoojúmọ́. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀.
Leviticus 24:3 in English
Leviticus 24:3 · Berean Standard Bible
Outside the veil of the Testimony * in the Tent of Meeting, Aaron is to tend the lamps continually before the LORD from evening until morning. This is to be a permanent statute for the generations to come.
Context
1Olúwa sọ fún Mose pé, 2“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti mú òróró tí ó mọ́ tí a fún láti ara olifi wá láti fi tan iná, kí fìtílà lè máa jò láì kú. 3Lẹ́yìn aṣọ ìkélé ti ibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Aaroni ti tan iná náà níwájú Olúwa, láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójoojúmọ́. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀. 4Àwọn Àtùpà tí wọ́n wà lórí ojúlówó ọ̀pá fìtílà tí a fi wúrà ṣe níwájú Olúwa ni kí ó máa jó lójoojúmọ́. 5“Mú ìyẹ̀fun dáradára, kí o sì ṣe ìṣù àkàrà méjìlá, kí o lo ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) fún ìṣù kọ̀ọ̀kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.