Lefitiku 23:5
Leviticus 23:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àjọ ìrékọjá Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní.
Leviticus 23:5 in English
Leviticus 23:5 · Berean Standard Bible
The Passover to the LORD begins at twilight on the fourteenth * day of the first month.
Context
3“ ‘Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ le fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi. Ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. Ọjọ́ ìsinmi Olúwa ni. 4“ ‘Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọdún tí Olúwa yàn, àjọ̀dún tí a yàn tí ẹ gbọdọ̀ kéde lákokò wọn. 5Àjọ ìrékọjá Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní. 6Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ni àjọ̀dún àkàrà àìwú tí Olúwa yó bẹ̀rẹ̀, fún ọjọ́ méje ni ẹ gbọdọ̀ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. 7Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan nínú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.