Native Bible

Leviticus 23:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò pa ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà run kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

Leviticus 23:30 in English

Leviticus 23:30 · Berean Standard Bible

I will destroy from among his people anyone who does any work on this day.

Context

28Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, torí pé ọjọ́ ètùtù ni, nínú èyí tí a ń ṣe ètùtù fún yín níwájú Olúwa Ọlọ́run yín. 29Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣẹ́ ara rẹ̀ ní ọjọ́ náà ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 30Èmi yóò pa ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà run kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 31Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan rárá. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. 32Ọjọ́ ìsinmi ni fún un yín, ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsànán oṣù náà, títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó tẹ̀lé e, ni kí ẹ fi sinmi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.