Lefitiku 22:16
Leviticus 22:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nípa fífi ààyè fún wọn láti jẹ ọrẹ mímọ́ náà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀bi tí wọn yóò san nǹkan fún wá sórí wọn. Èmi ni Olúwa, tí ó sọ wọ́n di mímọ́.’ ”
Leviticus 22:16 in English
Leviticus 22:16 · Berean Standard Bible
by allowing the people to eat the sacred offerings and thus to bear the punishment for guilt. For I am the LORD who sanctifies them.”
Context
14“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì jẹ ọrẹ mímọ́ kan, ó gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe lórí ẹbọ náà fún àlùfáà, kí ó sì fi ìdámárùn-ún ohun tí ọrẹ náà jẹ́ kún un. 15Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá síwájú Olúwa di àìmọ́. 16Nípa fífi ààyè fún wọn láti jẹ ọrẹ mímọ́ náà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀bi tí wọn yóò san nǹkan fún wá sórí wọn. Èmi ni Olúwa, tí ó sọ wọ́n di mímọ́.’ ” 17Olúwa sọ fún Mose pé, 18“Sọ fún Aaroni, àwọn ọmọ rẹ̀ àti fún gbogbo Israẹli kí o sì wí fún wọn pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín yálà ọmọ Israẹli ni tàbí àlejò tí ń gbé ní Israẹli bá mú ẹ̀bùn wá fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, yálà láti san ẹ̀jẹ́ tàbí ọrẹ àtinúwá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.