Native Bible

Leviticus 22:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá síwájú Olúwa di àìmọ́.

Leviticus 22:15 in English

Leviticus 22:15 · Berean Standard Bible

The priests must not profane the sacred offerings that the Israelites present to the LORD

Context

13Ṣùgbọ́n bí ọmọbìnrin àlùfáà bá jẹ́ opó tàbí tí a ti kọ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò lọ́mọ tí ó sì padà sínú ilé baba rẹ̀ láti máa gbé bẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀, ó le jẹ oúnjẹ baba rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àlejò tí kò lẹ́tọ̀ọ́ kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú oúnjẹ náà. 14“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì jẹ ọrẹ mímọ́ kan, ó gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe lórí ẹbọ náà fún àlùfáà, kí ó sì fi ìdámárùn-ún ohun tí ọrẹ náà jẹ́ kún un. 15Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá síwájú Olúwa di àìmọ́. 16Nípa fífi ààyè fún wọn láti jẹ ọrẹ mímọ́ náà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀bi tí wọn yóò san nǹkan fún wá sórí wọn. Èmi ni Olúwa, tí ó sọ wọ́n di mímọ́.’ ” 17Olúwa sọ fún Mose pé,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.