Native Bible

Leviticus 21:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ fá irun orí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ rẹ́ irùngbọ̀n rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara rẹ̀ láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀.

Leviticus 21:5 in English

Leviticus 21:5 · Berean Standard Bible

Priests must not make bald spots on their heads, shave off the edges of their beards, or make cuts in their bodies.

Context

3Tàbí fún arábìnrin rẹ̀ tí kò ì tí ì wọ ilé ọkọ tí ó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí tí arábìnrin bẹ́ẹ̀, ó lè sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. 4Nítorí tí ó jẹ́ olórí, òun kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ ba ara rẹ̀ jẹ́ láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 5“ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ fá irun orí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ rẹ́ irùngbọ̀n rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara rẹ̀ láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀. 6Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún Ọlọ́run, kí wọ́n má ba à sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di àìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń fi iná sun ẹbọ sí Olúwa wọn, ti ó jẹ oúnjẹ Ọlọ́run wọn. Nítorí náà wọn gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́. 7“ ‘Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ fẹ́ panṣágà tàbí obìnrin tí ó ti fi ọkùnrin ba ara rẹ̀ jẹ́ tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀sílẹ̀ nítorí pé àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.