Native Bible

Leviticus 21:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ó má ba à sọ di aláìmọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. Èmi ni Olúwa tí ó sọ ọ́ di mímọ́.’ ”

Leviticus 21:15 in English

Leviticus 21:15 · Berean Standard Bible

so that he does not defile his offspring among his people, for I am the LORD who sanctifies him.”

Context

13“ ‘Ọmọbìnrin tí yóò fẹ́ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí kò mọ ọkùnrin rí. 14Kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tàbí ẹni tí a kọ̀sílẹ̀ tàbí obìnrin tí ó ti fi àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n kí ó fẹ́ obìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí, láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 15Kí ó má ba à sọ di aláìmọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. Èmi ni Olúwa tí ó sọ ọ́ di mímọ́.’ ” 16Olúwa sì bá Mose sọ̀rọ̀ pé, 17“Sọ fún Aaroni pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú irú-ọmọ rẹ̀ ní ìran-ìran wọn, tí ó bá ní ààrùn kan, kí ó má ṣe súnmọ́ tòsí láti rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọ́run rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.