Lefitiku 21:14
Leviticus 21:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tàbí ẹni tí a kọ̀sílẹ̀ tàbí obìnrin tí ó ti fi àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n kí ó fẹ́ obìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí, láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
Leviticus 21:14 in English
Leviticus 21:14 · Berean Standard Bible
He is not to marry a widow, a divorced woman, or one defiled by prostitution. He is to marry a virgin from his own people,
Context
12Kò gbọdọ̀ kúrò ní ibi mímọ́ Ọlọ́run tàbí kí ó sọ ọ́ di aláìmọ́ torí pé a ti fi ìfòróróyàn Ọlọ́run yà á sí mímọ́. Èmi ni Olúwa. 13“ ‘Ọmọbìnrin tí yóò fẹ́ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí kò mọ ọkùnrin rí. 14Kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tàbí ẹni tí a kọ̀sílẹ̀ tàbí obìnrin tí ó ti fi àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n kí ó fẹ́ obìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí, láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 15Kí ó má ba à sọ di aláìmọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. Èmi ni Olúwa tí ó sọ ọ́ di mímọ́.’ ” 16Olúwa sì bá Mose sọ̀rọ̀ pé,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.