Lefitiku 20:12
Leviticus 20:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa, wọ́n ti ṣe ohun tí ó lòdì, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.
Leviticus 20:12 in English
Leviticus 20:12 · Berean Standard Bible
If a man lies with his daughter-in-law, both must surely be put to death. They have acted perversely; their blood is upon them.
Context
10“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀: ọkùnrin àti obìnrin náà ni kí ẹ sọ ní òkúta pa. 11“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀ ti tàbùkù baba rẹ̀. Àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn. 12“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa, wọ́n ti ṣe ohun tí ó lòdì, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn. 13“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin mìíràn lòpọ̀ bí wọ́n ti í bá obìnrin lòpọ̀: àwọn méjèèjì ti ṣe ohun ìríra, pípa ni kí ẹ pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn. 14“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ tìyátọmọ papọ̀, ìwà búburú ni èyí: iná ni kí ẹ fi sun wọ́n, òun àti àwọn méjèèjì, kí ìwà búburú má ba à gbilẹ̀ láàrín yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.