Native Bible

Leviticus 20:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀ ti tàbùkù baba rẹ̀. Àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

Leviticus 20:11 in English

Leviticus 20:11 · Berean Standard Bible

If a man lies with his father’s wife, he has uncovered his father’s nakedness. Both must surely be put to death; their blood is upon them.

Context

9“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé baba tàbí ìyá rẹ̀ ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí ara rẹ̀ torí pé ó ti ṣépè lé baba àti ìyá rẹ̀. 10“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀: ọkùnrin àti obìnrin náà ni kí ẹ sọ ní òkúta pa. 11“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀ ti tàbùkù baba rẹ̀. Àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn. 12“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa, wọ́n ti ṣe ohun tí ó lòdì, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn. 13“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin mìíràn lòpọ̀ bí wọ́n ti í bá obìnrin lòpọ̀: àwọn méjèèjì ti ṣe ohun ìríra, pípa ni kí ẹ pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.