Native Bible

Leviticus 19:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Ẹ má ṣe ba ọmọbìnrin yín jẹ́ láti sọ ọ́ di panṣágà, kí ilẹ̀ yín má ba à di ti àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà búburú.

Leviticus 19:29 in English

Leviticus 19:29 · Berean Standard Bible

You must not defile your daughter by making her a prostitute, or the land will be prostituted and filled with depravity.

Context

27“ ‘Ẹ má ṣe dá òṣù sí àárín orí yín (fífá irun ẹ̀gbẹ́ orí, tí a ó sì dá irun àárín orí sí) tàbí kí ẹ ré orí irùngbọ̀n yín bí àwọn aláìkọlà ti ń ṣe. 28“ ‘Ẹ má ṣe tìtorí òkú, gé ibi kankan nínú ẹ̀yà ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ sín gbẹ́rẹ́ kankan. Èmi ni Olúwa. 29“ ‘Ẹ má ṣe ba ọmọbìnrin yín jẹ́ láti sọ ọ́ di panṣágà, kí ilẹ̀ yín má ba à di ti àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà búburú. 30“ ‘Ẹ gbọdọ̀ máa pa ìsinmi mi mọ́ kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi. Èmi ni Olúwa. 31“ ‘Ẹ má ṣe tọ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn àjẹ́ lọ, ẹ kò gbọdọ̀ tọ̀ wọ́n lẹ́yìn láti jẹ́ kí wọ́n sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.