Lefitiku 18:14
Leviticus 18:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù arákùnrin baba rẹ nípa sísún mọ́ aya rẹ̀ láti bá a lòpọ̀ nítorí pé ìyàwó ẹ̀gbọ́n baba rẹ ni.
Leviticus 18:14 in English
Leviticus 18:14 · Berean Standard Bible
You must not dishonor your father’s brother by approaching his wife to have sexual relations with her; she is your aunt.
Context
12“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin baba rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan baba rẹ ni. 13“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin màmá rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan ìyá rẹ ni. 14“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù arákùnrin baba rẹ nípa sísún mọ́ aya rẹ̀ láti bá a lòpọ̀ nítorí pé ìyàwó ẹ̀gbọ́n baba rẹ ni. 15“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọ àna obìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé aya ọmọ rẹ ni. Má ṣe bá a lòpọ̀. 16“ ‘Má ṣe bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ ọkùnrin lòpọ̀ nítorí pé yóò tàbùkù ẹ̀gbọ́n rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.