Native Bible

Leviticus 17:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

bí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé Israẹli bá pa màlúù tàbí ọ̀dọ́-àgùntàn tàbí àgbò nínú ibùdó tàbí bí ó bá pa á lẹ́yìn ibùdó

Leviticus 17:3 in English

Leviticus 17:3 · Berean Standard Bible

‘Anyone from the house of Israel who slaughters an ox,* a lamb, or a goat in the camp or outside of it

Context

1Olúwa sọ fún Mose pé, 2“Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: ‘Ohun tí Olúwa pàṣẹ nìyí, 3bí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé Israẹli bá pa màlúù tàbí ọ̀dọ́-àgùntàn tàbí àgbò nínú ibùdó tàbí bí ó bá pa á lẹ́yìn ibùdó 4tí kò sì mú un wá sí ibi àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa níwájú àgọ́ ìpàdé, ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni kí ẹ kà sí ẹni náà lọ́rùn: torí pé ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹni náà ni a ó sì gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 5Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àwọn ọmọ Israẹli le è máa mú ẹbọ wọn tí wọn ti rú ní ìta gbangba wá sí iwájú Olúwa: wọ́n gbọdọ̀ mú un wá síwájú àlùfáà àní sí Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n sì rú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.