Lefitiku 14:37
Leviticus 14:37 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Yóò yẹ ààrùn náà wò, bí ààrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa àmì àwọ̀ ewé tàbí àmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ.
Leviticus 14:37 in English
Leviticus 14:37 · Berean Standard Bible
He is to examine the house, and if the mildew on the walls consists of green or red depressions that appear to be beneath the surface of the wall,
Context
35Kí ẹni tí ó ní ilé náà lọ sọ fún àlùfáà pé, ‘Èmi tí rí ohun tí ó jọ ààrùn ẹ̀tẹ̀ ní ilé mi.’ 36Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má bá à di àìmọ́. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò. 37Yóò yẹ ààrùn náà wò, bí ààrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa àmì àwọ̀ ewé tàbí àmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ. 38Àlùfáà yóò jáde kúrò nínú ilé náà, yóò sì ti ìlẹ̀kùn ilé náà pa fún ọjọ́ méje. 39Àlùfáà yóò padà wá yẹ ilé náà wò ní ọjọ́ keje. Bí ààrùn náà bá ti tàn ká ara ògiri.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.