Native Bible

Leviticus 14:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ẹni tí ó ní ilé náà lọ sọ fún àlùfáà pé, ‘Èmi tí rí ohun tí ó jọ ààrùn ẹ̀tẹ̀ ní ilé mi.’

Leviticus 14:35 in English

Leviticus 14:35 · Berean Standard Bible

the owner of the house shall come and tell the priest, ‘Something like mildew has appeared in my house.’

Context

33Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé. 34“Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fi fún yín ní ìní, tí mo sì fi ààrùn ẹ̀tẹ̀ sínú ilé kan ní ilẹ̀ ìní yín. 35Kí ẹni tí ó ní ilé náà lọ sọ fún àlùfáà pé, ‘Èmi tí rí ohun tí ó jọ ààrùn ẹ̀tẹ̀ ní ilé mi.’ 36Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má bá à di àìmọ́. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò. 37Yóò yẹ ààrùn náà wò, bí ààrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa àmì àwọ̀ ewé tàbí àmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.