Native Bible

Leviticus 13:53 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí ẹ̀tẹ̀ náà kò ràn ká ara aṣọ náà yálà aṣọ títa, aṣọ híhun tàbí aláwọ.

Leviticus 13:53 in English

Leviticus 13:53 · Berean Standard Bible

But when the priest reexamines it, if the mildew has not spread in the fabric, weave, knit, or leather article,

Context

51Ní ọjọ́ keje kí ó yẹ̀ ẹ́ wò bí ààrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá ràn ká ara aṣọ tàbí irun àgùntàn, aṣọ híhun tàbí awọ, bí ó ti wù kí ó wúlò tó, ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí jẹ́, irú ohun bẹ́ẹ̀ kò mọ́. 52Ó gbọdọ̀ sun aṣọ náà tàbí irun àgùntàn náà, aṣọ híhun náà tàbí awọ náà ti ó ni ààrùn kan lára rẹ̀ ni iná torí pé ààrùn ẹ̀tẹ̀ tí í pa ni run ni. Gbogbo nǹkan náà ni ẹ gbọdọ̀ sun ní iná. 53“Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí ẹ̀tẹ̀ náà kò ràn ká ara aṣọ náà yálà aṣọ títa, aṣọ híhun tàbí aláwọ. 54Kí ó pàṣẹ pé kí wọ́n fọ ohunkóhun tí ó bàjẹ́ náà kí ó sì wà ní ìpamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn. 55Lẹ́yìn tí ẹ bá ti fọ ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà mú tan, kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ẹ̀tẹ̀ náà kò bá yí àwọn aṣọ náà padà, bí kò tilẹ̀ tí ì ràn, àìmọ́ ni ó jẹ́. Ẹ fi iná sun un, yálà ẹ̀gbẹ́ kan tàbí òmíràn ni ẹ̀tẹ̀ náà dé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.