Native Bible

Leviticus 13:52 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó gbọdọ̀ sun aṣọ náà tàbí irun àgùntàn náà, aṣọ híhun náà tàbí awọ náà ti ó ni ààrùn kan lára rẹ̀ ni iná torí pé ààrùn ẹ̀tẹ̀ tí í pa ni run ni. Gbogbo nǹkan náà ni ẹ gbọdọ̀ sun ní iná.

Leviticus 13:52 in English

Leviticus 13:52 · Berean Standard Bible

He is to burn the fabric, weave, or knit, whether the contaminated item is wool or linen or leather. Since the mildew is harmful, the article must be burned up.

Context

50Àlùfáà yóò yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, yóò sì pa gbogbo ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà ti ràn mọ́ fún ọjọ́ méje. 51Ní ọjọ́ keje kí ó yẹ̀ ẹ́ wò bí ààrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá ràn ká ara aṣọ tàbí irun àgùntàn, aṣọ híhun tàbí awọ, bí ó ti wù kí ó wúlò tó, ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí jẹ́, irú ohun bẹ́ẹ̀ kò mọ́. 52Ó gbọdọ̀ sun aṣọ náà tàbí irun àgùntàn náà, aṣọ híhun náà tàbí awọ náà ti ó ni ààrùn kan lára rẹ̀ ni iná torí pé ààrùn ẹ̀tẹ̀ tí í pa ni run ni. Gbogbo nǹkan náà ni ẹ gbọdọ̀ sun ní iná. 53“Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí ẹ̀tẹ̀ náà kò ràn ká ara aṣọ náà yálà aṣọ títa, aṣọ híhun tàbí aláwọ. 54Kí ó pàṣẹ pé kí wọ́n fọ ohunkóhun tí ó bàjẹ́ náà kí ó sì wà ní ìpamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.