Lefitiku 11:38
Leviticus 11:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ti da omi sí ohun ọ̀gbìn náà tí òkú wọn sì bọ́ sí orí rẹ̀ àìmọ́ ni èyí fún un yín.
Leviticus 11:38 in English
Leviticus 11:38 · Berean Standard Bible
but if water has been put on the seed and a carcass falls on it, it is unclean for you.
Context
36Bí òkú wọn bá bọ́ sínú omi tàbí kànga tó ní omi nínú, omi náà kò di aláìmọ́ ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá yọ òkú wọn jáde tí ó fi ọwọ́ kàn án yóò di aláìmọ́. 37Bí òkú ẹranko wọ̀nyí bá bọ́ sórí ohun ọ̀gbìn tí ẹ fẹ́ gbìn wọ́n sì jẹ́ mímọ́. 38Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ti da omi sí ohun ọ̀gbìn náà tí òkú wọn sì bọ́ sí orí rẹ̀ àìmọ́ ni èyí fún un yín. 39“ ‘Bí ẹran kan bá kú nínú àwọn tí ẹ lè jẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú rẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 40Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èyíkéyìí nínú òkú ẹranko náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú ẹranko yóò fọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wà ní àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.