Native Bible

Leviticus 10:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ gbọdọ̀ kọ́ àwọn ara Israẹli ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún wọn láti ẹnu Mose.”

Leviticus 10:11 in English

Leviticus 10:11 · Berean Standard Bible

so that you may teach the Israelites all the statutes that the LORD has given them through Moses.”

Context

9“Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle mìíràn nígbàkígbà tí ẹ bá n lọ inú àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kù ú, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín láti ìrandíran. 10Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrín mímọ́ àti àìmọ́, láàrín èérí àti àìléèérí. 11Ẹ gbọdọ̀ kọ́ àwọn ara Israẹli ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún wọn láti ẹnu Mose.” 12Mose sì sọ fún Aaroni, Eleasari àti Itamari àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù pé, “Ẹ mú ẹbọ ohun jíjẹ tó ṣẹ́kù láti inú ẹbọ àfinásun sí Olúwa, kí ẹ jẹ ẹ́ láìní ìwúkàrà nínú, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ nítorí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. 13Ẹ jẹ́ ní ibi mímọ́, nítorí pé òun ni ìpín rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nínú ẹbọ tí a finá sun sí Olúwa nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe pa á láṣẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.