Native Bible

Lamentations 4:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìjìyà àwọn ènìyàn mi tóbi ju ti Sodomu lọ, tí a sí ní ipò ní òjijì láìsí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́.

Lamentations 4:6 in English

Lamentations 4:6 · Berean Standard Bible

The punishment * of the daughter of my people is greater than that of Sodom, which was overthrown in an instant without a hand turned to help her.

Context

4Nítorí òǹgbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́ lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn; àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fi fún wọn. 5Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradára di òtòṣì ní òpópó. Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀ ni wọ́n sùn ní orí òkìtì eérú. 6Ìjìyà àwọn ènìyàn mi tóbi ju ti Sodomu lọ, tí a sí ní ipò ní òjijì láìsí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́. 7Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò-dídì, wọ́n sì funfun ju wàrà lọ wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa, ìrísí wọn dàbí safire. 8Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n dúdú ju èédú; wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó. Ara wọn hun mọ́ egungun; ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.