Ẹkún Jeremiah 4:1
Lamentations 4:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù, wúrà dídára di àìdán! Òkúta ibi mímọ́ wá túká sí oríta gbogbo òpópó.
Lamentations 4:1 in English
Lamentations 4:1 · Berean Standard Bible
How * the gold has become tarnished, the pure gold has become dull! The gems of the temple lie scattered on every street corner.
Context
1Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù,
wúrà dídára di àìdán!
Òkúta ibi mímọ́ wá túká
sí oríta gbogbo òpópó. 2Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Sioni tí ó ṣe iyebíye,
tí wọ́n fi wúrà dídára ṣe
wá dàbí ìkòkò amọ̀ lásán
iṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò! 3Àwọn ajáko pèsè ọmú wọn
fún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn,
ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kàn
bí ògòǹgò ní aginjù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.