Ẹkún Jeremiah 2:16
Lamentations 2:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn gbòòrò sí ọ; wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payínkeke wọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán. Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí; tí a sì wá láti rí.”
Lamentations 2:16 in English
Lamentations 2:16 · Berean Standard Bible
All your enemies open their mouths against you. They hiss and gnash their teeth, saying, “We have swallowed her up. This is the day for which we have waited. We have lived to see it!”
Context
14Ìran àwọn wòlíì rẹ
jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n;
wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn
tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ.
Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ
jẹ́ èké àti ìmúniṣìnà. 15Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ
pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí;
wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn
sí ọmọbìnrin Jerusalẹmu:
“Èyí ha ni ìlú tí à ń pè
ní àṣepé ẹwà,
ìdùnnú gbogbo ayé?” 16Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn
gbòòrò sí ọ;
wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payínkeke
wọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán.
Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí;
tí a sì wá láti rí.” 17Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu;
ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,
tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́.
Ó ti ṣí ọ ní ipò láì láàánú,
ó fún ọ̀tá ní ìṣẹ́gun lórí rẹ,
ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga. 18Ọkàn àwọn ènìyàn
kígbe jáde sí Olúwa.
Odi ọmọbìnrin Sioni,
jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odò
ní ọ̀sán àti òru;
má ṣe fi ara rẹ fún ìtura,
ojú rẹ fún ìsinmi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.