Ẹkún Jeremiah 1:15
Lamentations 1:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Olúwa kọ àwọn akọni mi sílẹ̀, ó rán àwọn ológun lòdì sí mi kí wọn pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi run. Nínú ìfúntí wáìnì rẹ̀ Olúwa tẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Juda.
Lamentations 1:15 in English
Lamentations 1:15 · Berean Standard Bible
The Lord has rejected all the mighty men in my midst; He has summoned an army against me * to crush my young warriors. Like grapes in a winepress, the Lord has trampled the Virgin Daughter of Judah.
Context
13“Ó rán iná láti òkè
sọ̀kalẹ̀ sínú egungun ara mi.
Ó dẹ àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi,
ó sì yí mi padà.
Ó ti pa mí lára
mó ń kú lọ ní gbogbo ọjọ́. 14“Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti di sísopọ̀ sí àjàgà;
ọwọ́ rẹ̀ ni a fi hun ún papọ̀.
Wọ́n ti yí ọrùn mi ká
Olúwa sì ti dín agbára mi kù.
Ó sì ti fi mí lé
àwọn tí n kò le dojúkọ lọ́wọ́. 15“Olúwa kọ
àwọn akọni mi sílẹ̀,
ó rán àwọn ológun lòdì sí mi
kí wọn pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi run.
Nínú ìfúntí wáìnì rẹ̀ Olúwa tẹ́
àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Juda. 16“Ìdí nìyí tí mo fi ń sọkún
tí omijé sì ń dà lójú mi.
Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sí mi,
kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà.
Àwọn ọmọ mi di aláìní
nítorí ọ̀tá ti borí.” 17Sioni na ọwọ́ jáde,
ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un.
Olúwa ti pàṣẹ fún Jakọbu
pé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀tá fún un
Jerusalẹmu ti di
ohun aláìmọ́ láàrín wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.